1. Kro 2:17-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Abigaili si bi Amasa: baba Amasa si ni Jeteri ara Iṣmeeli.

18. Kalebu ọmọ Hesroni si bi ọmọ lati ọdọ Asuba aya rẹ̀, ati lati ọdọ Jeriotu: awọn ọmọ rẹ̀ ni wọnyi; Jeṣeri, ati Ṣohabu, ati Ardoni.

19. Nigbati Asuba kú, Kalebu mu Efrati, ẹniti o bi Huri fun u.

20. Huri si bi Uru, Uru si bi Besaleeli.

21. Lẹhin na Hesroni si wọle tọ̀ ọmọ Makiri obinrin baba Gileadi, on gbe e ni iyawo nigbati o di ẹni ọgọta ọdun, on si bi Segubu fun u.

1. Kro 2