1. Kro 2:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WỌNYI ni awọn ọmọ Israeli; Rubeni, Simeoni, Lefi, ati Juda, Issakari, ati Sebuluni,

2. Dani, Josefu, ati Benjamini, Naftali, Gadi, ati Aṣeri.

3. Awọn ọmọ Juda; Eri, ati Onani, ati Ṣela; awọn mẹta yi ni Batṣua, ara Kenaani, bi fun u. Eri, akọbi Juda, si buru loju Oluwa; on si pa a.

4. Tamari aya-ọmọ rẹ̀ si bi Faresi ati Sera fun u. Gbogbo awọn ọmọ Juda jẹ marun.

5. Awọn ọmọ Faresi; Hesroni; ati Hamuli.

6. Ati awọn ọmọ Sera; Simri, ati Etani, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara: gbogbo wọn jẹ marun.

7. Ati awọn ọmọ Karmi; Akari, oniyọnu Israeli, ẹniti o dẹṣẹ niti ohun iyasọtọ̀.

1. Kro 2