1. ATI emi, ará, nigbati mo tọ̀ nyin wá, kì iṣe ọ̀rọ giga ati ọgbọ́n giga ni mo fi tọ̀ nyin wá, nigbati emi nsọ̀rọ ohun ijinlẹ Ọlọrun fun nyin.
2. Nitori mo ti pinnu rẹ̀ pe, emi kì yio mọ̀ ohunkohun larin nyin, bikoṣe Jesu Kristi, ẹniti a kàn mọ agbelebu.
3. Emi si wà pẹlu nyin ni ailera, ati ni ẹ̀ru, ati ni ọ̀pọlọpọ iwarìri.
4. Ati ọ̀rọ mi, ati iwasu mi kì iṣe nipa ọ̀rọ ọgbọ́n enia, ti a fi nyi ni lọkàn pada, bikoṣe nipa ifihan ti Ẹmí ati ti agbara:
5. Ki igbagbọ́ nyin ki o máṣe duro ninu ọgbọ́n enia, bikoṣe ninu agbara Ọlọrun.
6. Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n larin awọn ti o pé: ṣugbọn kì iṣe ọgbọ́n ti aiye yi, tabi ti awọn olori aiye yi, ti o di asan:
7. Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n Ọlọrun ni ijinlẹ, ani ọgbọ́n ti o farasin, eyiti Ọlọrun ti làna silẹ ṣaju ipilẹṣẹ aiye fun ogo wa: