1. Kor 12:1-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ niti ẹbun ẹmí, ará, emi kò fẹ ki ẹnyin ki o jẹ ope.

2. Ẹnyin mọ̀ pe nigbati ẹnyin jẹ Keferi, a fà nyin lọ sọdọ awọn odi oriṣa, lọnakọna ti a fa nyin.

3. Nitorina mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe, kò si ẹniti nsọ̀rọ nipa Ẹmí Ọlọrun ki o wipe ẹni ifibu ni Jesu: ati pe, kò si ẹniti o le wipe, Oluwa ni Jesu, bikoṣe nipa Ẹmí Mimọ́.

4. Njẹ onirũru ẹ̀bun li o wà, ṣugbọn Ẹmí kanna ni.

5. Onirũru iṣẹ-iranṣẹ li ó si wà, Oluwa kanna si ni.

6. Onirũru iṣẹ li o si wà, ṣugbọn Ọlọrun kanna ni ẹniti nṣiṣẹ gbogbo wọn ninu gbogbo wọn.

7. Ṣugbọn a nfi ifihàn Ẹmí fun olukuluku enia lati fi jère.

8. Nitoriti a fi ọ̀rọ ọgbọ́n fun ẹnikan nipa Ẹmí; ati fun ẹlomiran ọ̀rọ-ìmọ nipa Ẹmí kanna;

9. Ati fun ẹlomiran igbagbọ́ nipa Ẹmí kanna; ati fun ẹlomiran ẹ̀bun imularada nipa Ẹmí kanna;

10. Ati fun ẹlomiran iṣẹ iyanu iṣe; ati fun ẹlomiran isọtẹlẹ; ati fun ẹlomiran ìmọ ẹmí yatọ; ati fun ẹlomiran onirũru ède; ati fun ẹlomiran itumọ̀ ède:

11. Ṣugbọn gbogbo wọnyi li ẹnikan nì, ani Ẹmí kanna nṣe, o npín fun olukuluku gẹgẹ bi o ti wù u.

12. Nitori gẹgẹ bi ara ti jẹ ọ̀kan, ti o si li ẹ̀ya pupọ, ṣugbọn ti gbogbo ẹ̀ya ara ti iṣe pupọ jẹ́ ara kan: bẹ̃ si ni Kristi pẹlu.

13. Nitoripe ninu Ẹmí kan li a ti baptisi gbogbo wa sinu ara kan, iba ṣe Ju, tabi Hellene, iba ṣe ẹrú, tabi omnira; a si ti mú gbogbo wa mu ninu Ẹmí kan.

14. Nitoripe ara kì iṣe ẹ̀ya kan, bikoṣe pupọ.

15. Bi ẹsẹ ba wipe, Nitori emi kì iṣe ọwọ́, emi kì iṣe ti ara; eyi kò wipe ki iṣe ti ara.

16. Bi etí ba si wipe, Nitori emi ki iṣe oju, emi kì iṣe ti ara: eyi kò wipe ki iṣe ti ara.

17. Bi gbogbo ara ba jẹ oju, nibo ni igbọràn iba gbé wà? Bi gbogbo rẹ̀ ba si jẹ igbọràn, nibo ni igbõrùn iba gbé wà?

18. Ṣugbọn nisisiyi Ọlọrun ti fi awọn ẹ̀ya sinu ara, olukuluku wọn gẹgẹ bi o ti wù u.

19. Bi gbogbo wọn ba si jẹ ẹ̀ya kan, nibo li ara iba gbé wà?

20. Ṣugbọn nisisiyi, nwọn jẹ ẹya pupọ, ṣugbọn ara kan.

21. Oju kò si le wi fun ọwọ́ pe, emi kò ni ifi ọ ṣe: tabi ki ori wi ẹ̀wẹ fun ẹsẹ pe, emi kò ni ifi nyin ṣe.

1. Kor 12