1. OLUKULUKU ẹniti o ba gbagbọ́ pe Jesu ni Kristi, a bí i nipa ti Ọlọrun: ati gbogbo ẹniti o fẹran ẹniti o bí ni, o fẹran ẹniti a bí nipasẹ rẹ̀ pẹlu.
2. Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa fẹran awọn ọmọ Ọlọrun, nigbati awa fẹran Ọlọrun, ti a si npa ofin rẹ̀ mọ́.
3. Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ̀ mọ́: ofin rẹ̀ kò si nira.
4. Nitori olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun o ṣẹgun aiye: eyi si ni iṣẹgun ti o ṣẹgun aiye, ani igbagbọ́ wa.
5. Tani ẹniti o ṣẹgun aiye, bikoṣe ẹniti o gbagbọ́ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu iṣe?
6. Eyi li ẹniti o wá, pẹlu omi ati ẹjẹ̀, ani Jesu Kristi, kì iṣe pẹlu omi nikan, bikoṣe pẹlu omi ati ẹ̀jẹ. Ẹmí li o si njẹri, nitoripe otitọ li Ẹmí.