1. OLUKULUKU ẹniti o ba gbagbọ́ pe Jesu ni Kristi, a bí i nipa ti Ọlọrun: ati gbogbo ẹniti o fẹran ẹniti o bí ni, o fẹran ẹniti a bí nipasẹ rẹ̀ pẹlu.
2. Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa fẹran awọn ọmọ Ọlọrun, nigbati awa fẹran Ọlọrun, ti a si npa ofin rẹ̀ mọ́.
3. Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ̀ mọ́: ofin rẹ̀ kò si nira.
4. Nitori olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun o ṣẹgun aiye: eyi si ni iṣẹgun ti o ṣẹgun aiye, ani igbagbọ́ wa.