1. Joh 2:10-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ẹniti o ba fẹran arakunrin rẹ̀, o ngbe inu imọlẹ, kò si si ohun ikọsẹ̀ ninu rẹ̀.

11. Ṣugbọn ẹniti o ba korira arakunrin rẹ̀ o ngbe inu òkunkun, o si nrìn ninu òkunkun, kò si mọ̀ ibiti on nrè, nitoriti òkunkun ti fọ ọ li oju.

12. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọmọ mi, nitoriti a dari ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin nitori orukọ rẹ̀.

13. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin baba, nitoriti ẹnyin ti mọ̀ ẹniti o wà li àtetekọṣe. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin ti ṣẹgun ẹni buburu nì. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọmọ mi, nitori ẹnyin ti mọ̀ Baba.

14. Emi kọwe si nyin, ẹnyin baba, nitoriti ẹnyin ti mọ̀ ẹniti o wà li àtetekọṣe. Emi ti kọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin li agbara, ti ọ̀rọ Ọlọrun si duro ninu nyin, ti ẹ si ṣẹgun ẹni buburu nì.

15. Ẹ máṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aiye, ifẹ ti Baba kò si ninu rẹ̀.

16. Nitori ohun gbogbo ti mbẹ li aiye, ifẹkufẹ ara, ati ifẹkufẹ oju, ati irera aiye, ki iṣe ti Baba, bikoṣe ti aiye.

17. Aiye si nkọja lọ, ati ifẹkufẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ifẹ Ọlọrun ni yio duro lailai.

18. Ẹnyin ọmọ mi, igba ikẹhin li eyi: bi ẹnyin si ti gbọ́ pe Aṣodisi-Kristi mbọ̀wá, ani nisisiyi Aṣodisi-Kristi pupọ̀ ni mbẹ; nipa eyiti awa fi mọ̀ pe igba ikẹhin li eyi.

19. Nwọn ti ọdọ wa jade, ṣugbọn nwọn ki iṣe ará wa; nitori nwọn iba ṣe ará wa, nwọn iba bá wa duro: ṣugbọn nwọn jade ki a le fi wọn hàn pe gbogbo nwọn ki iṣe ará wa.

20. Ṣugbọn ẹnyin ni ifororo-yan lati ọdọ Ẹni Mimọ́ nì wá, ẹnyin si mọ̀ ohun gbogbo.

21. Emi kò kọwe si nyin nitoripe ẹnyin kò mọ̀ otitọ, ṣugbọn nitoriti ẹnyin mọ̀ ọ, ati pe kò si eke ninu otitọ.

22. Tani eke, bikoṣe ẹniti o ba sẹ́ pe Jesu kì iṣe Kristi? Eleyi ni Aṣodisi-Kristi, ẹniti o ba sẹ́ Baba ati Ọmọ.

23. Ẹnikẹni ti o ba sẹ́ Ọmọ, on na ni kò gbà Baba: ṣugbọn ẹniti o ba jẹwọ Ọmọ, o gbà Baba pẹlu.

1. Joh 2