32. Ilẹkùn mejeji na li o si fi igi olifi ṣe; o si yá aworan awọn kerubu ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko sara wọn, o si fi wura bò wọn, o si nà wura si ara awọn kerubu, ati si ara igi-ọpẹ.
33. Bẹ̃li o si ṣe opó igi olifi olorigun mẹrin fun ilẹkun tempili na.
34. Ilẹkun mejeji si jẹ ti igi firi: awẹ́ meji ilẹkun kan jẹ iṣẹ́po, ati awẹ́ meji ilẹkun keji si jẹ iṣẹ́po.
35. O si yá awọn kerubu, ati igi-ọpẹ, ati itanna eweko si ara wọn: o si fi wura bò o, eyi ti o tẹ́ sori ibi ti o gbẹ́.