1. A. Ọba 6:28-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. O si fi wura bò awọn kerubu na.

29. O si yá aworan awọn kerubu lara gbogbo ogiri ile na yikakiri ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko, ninu ati lode.

30. Ilẹ ile na li o fi wura tẹ́ ninu ati lode.

31. Ati fun oju-ọ̀na ibi-mimọ́-julọ li o ṣe ilẹkùn igi olifi: itẹrigbà ati opó ihà jẹ idamarun ogiri.

32. Ilẹkùn mejeji na li o si fi igi olifi ṣe; o si yá aworan awọn kerubu ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko sara wọn, o si fi wura bò wọn, o si nà wura si ara awọn kerubu, ati si ara igi-ọpẹ.

33. Bẹ̃li o si ṣe opó igi olifi olorigun mẹrin fun ilẹkun tempili na.

34. Ilẹkun mejeji si jẹ ti igi firi: awẹ́ meji ilẹkun kan jẹ iṣẹ́po, ati awẹ́ meji ilẹkun keji si jẹ iṣẹ́po.

35. O si yá awọn kerubu, ati igi-ọpẹ, ati itanna eweko si ara wọn: o si fi wura bò o, eyi ti o tẹ́ sori ibi ti o gbẹ́.

1. A. Ọba 6