2. Elijah si lọ ifi ara rẹ̀ han Ahabu. Iyan nla si mu ni Samaria.
3. Ahabu si pe Obadiah, ti iṣe olori ile rẹ̀. Njẹ Obadiah bẹ̀ru Oluwa gidigidi:
4. O si ṣe, nigbati Jesebeli ke awọn woli Oluwa kuro, ni Obadiah mu ọgọrun woli, o si fi wọn pamọ li aradọta ni iho okuta; o si fi àkara pẹlu omi bọ́ wọn.
5. Ahabu si wi fun Obadiah pe, Rin ilẹ lọ, si orisun omi gbogbo, ati si odò gbogbo: bọya awa le ri koriko lati gbà awọn ẹṣin ati awọn ibãka là, ki a má ba ṣòfo awọn ẹranko patapata.
6. Nwọn si pin ilẹ na lãrin ara wọn, lati là a ja: Ahabu gba ọ̀na kan lọ fun ara rẹ̀, Obadiah si gba ọ̀na miran lọ fun ara rẹ̀.