6. Awọn ẹiyẹ iwò si mu akara pẹlu ẹran fun u wá li owurọ, ati akara ati ẹran li alẹ: on si mu ninu odò na.
7. O si ṣe lẹhin ọjọ wọnni, odò na si gbẹ, nitoriti kò si òjo ni ilẹ na.
8. Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá wipe,
9. Dide, lọ si Sarefati ti Sidoni, ki o si ma gbe ibẹ: kiyesi i, emi ti paṣẹ fun obinrin opó kan nibẹ lati ma bọ́ ọ.
10. On si dide, o si lọ si Sarefati. Nigbati o si de ibode ilu na, kiyesi i, obinrin opó kan nṣa igi jọ nibẹ: o si ke si i, o si wipe, Jọ̃, bu omi diẹ fun mi wá ninu ohun-elo, ki emi ki o le mu.