20. Kiniun mejila duro nibẹ niha ekini ati ekeji lori atẹgùn mẹfa na: a kò ṣe iru rẹ̀ ni ijọba kan.
21. Ati gbogbo ohun-elo mimu Solomoni ọba jẹ wura, ati gbogbo ohun-elo ile igbo Lebanoni jẹ wura daradara; kò si fadaka; a kò kà a si nkankan li ọjọ Solomoni.
22. Nitori ọba ni ọkọ̀ Tarṣiṣi kan pẹlu ọkọ̀ Hiramu li okun: ẹ̃kan li ọdun mẹta li ọkọ̀ Tarṣiṣi idé, ti imu wura ati fadaka, ehin-erin ati inakí ati ẹiyẹ-ologe wá.
23. Solomoni ọba si pọ̀ jù gbogbo awọn ọba aiye lọ, li ọrọ̀ ati li ọgbọ́n.