38. Sadoku alufa, ati Natani woli, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati awọn ara Kereti ati Peleti si sọkalẹ, nwọn si mu ki Solomoni ki o gùn ibãka Dafidi ọba, nwọn si mu u wá si Gihoni,
39. Sadoku alufa si mu iwo ororo lati inu agọ, o si dà a si Solomoni lori; nwọn si fun fère; gbogbo enia si wipe, Ki Solomoni ọba ki o pẹ.
40. Gbogbo enia si goke tọ̀ ọ lẹhin, awọn enia si fun ipè, nwọn si yọ̀ ayọ̀ nlanla, tobẹ̃ ti ilẹ mì fun iró wọn.
41. Ati Adonijah ati gbogbo awọn ti o pè sọdọ rẹ̀ si gbọ́, nigbati nwọn jẹun tan, Joabu si gbọ́ iró ipè o si wipe: eredi ariwo ilu ti nrọkẹkẹ yi?
42. Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, Jonatani, ọmọ Abiatari, alufa de; Adonijah si wi fun u pe, Mã wolẹ̀; nitoripe alagbara ọkunrin ni iwọ, ati ẹniti nmu ihin-rere wá.
43. Jonatani si dahùn o si wi fun Adonijah pe, Lõtọ ni, oluwa wa, Dafidi ọba, fi Solomoni jọba.