10. Ṣugbọn Natani, alufa, ati Benaiah ati awọn ọkunrin alagbara, ati Solomoni arakunrin rẹ̀ ni kò pè.
11. Natani si wi fun Batṣeba, iya Solomoni pe, Iwọ kò gbọ́ pe, Adonijah, omọ Haggiti jọba, Dafidi, oluwa wa, kò si mọ̀?
12. Nitorina, wá nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, emi o si fun ọ ni ìmọ, ki iwọ ki o le gbà ẹmi rẹ là, ati ẹmi Solomoni ọmọ rẹ.
13. Lọ, ki o si tọ̀ Dafidi, ọba lọ, ki o si wi fun u pe, Ọba, oluwa mi, ṣe iwọ li o bura fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, pe, nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, ni yio jọba lẹhin mi, on ni o si joko lori itẹ mi? ẽṣe ti Adonijah fi jọba?
14. Kiyesi i, bi iwọ ti mba ọba sọ̀rọ lọwọ, emi o si tẹle ọ, emi o si wá ikún ọ̀rọ rẹ.
15. Batṣeba si tọ̀ ọba lọ ni iyẹ̀wu: ọba si gbó gidigidi: Abiṣagi, ara Ṣunemu, si nṣe iranṣẹ fun ọba.
16. Batṣeba si tẹriba, o si wolẹ fun ọba. Ọba si wipe, Kini iwọ nfẹ?
17. On si wi fun u pe, oluwa mi, iwọ fi Oluwa Ọlọrun rẹ bura fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin pe, nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, yio jọba lẹhin mi, on o si joko lori itẹ mi.
18. Sa wò o, nisisiyi, Adonijah jọba; iwọ, oluwa mi ọba, kò si mọ̀.
19. O si pa malu ati ẹran ti o li ọra, ati agùtan li ọ̀pọlọpọ, o si pe gbogbo awọn ọmọ ọba, ati Abiatari alufa, ati Joabu balogun: ṣugbọn Solomoni iranṣẹ rẹ ni kò pè.
20. Ati iwọ, oluwa mi, ọba, oju gbogbo Israeli mbẹ lara rẹ, ki iwọ ki o sọ fun wọn, tani yio joko lori itẹ oluwa mi ọba lẹhin rẹ̀?
21. Yio si ṣe, nigbati oluwa mi ọba ba sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a o si kà emi ati Solomoni ọmọ mi si ẹlẹṣẹ̀.