1. A. Ọba 1:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. DAFIDI ọba si di arugbo, ọjọ rẹ̀ si pọ̀; nwọn si fi aṣọ bò o lara, ṣugbọn kò mõru.

2. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Jẹ ki a wá ọmọbinrin kan, wundia, fun Oluwa mi, ọba: ki o si duro niwaju ọba, ki o si ṣikẹ́ rẹ̀, ki o si dubulẹ li õkan-aiya rẹ̀, oluwa mi, ọba yio si mõru.

3. Nwọn si wá ọmọbinrin arẹwà kan ka gbogbo agbegbe Israeli, nwọn si ri Abiṣagi, ara Ṣunemu, nwọn si mu u tọ̀ ọba wá.

4. Ọmọbinrin na si ṣe arẹwà gidigidi, o si nṣikẹ́ ọba, o si nṣe iranṣẹ fun u; ṣugbọn ọba kò si mọ̀ ọ.

5. Adonijah, ọmọ Haggiti, si gbe ara rẹ̀ ga, wipe, emi ni yio jọba: o si mura kẹkẹ́ ati awọn ẹlẹṣin, ati ãdọta ọkunrin lati sare niwaju rẹ̀.

6. Baba rẹ̀ kò si bà a ninu jẹ rí, pe, Ẽṣe ti iwọ fi ṣe bayi? On si ṣe enia ti o dara gidigidi: iya rẹ̀ si bi i le Absalomu.

7. O si ba Joabu, ọmọ Seruiah, ati Abiatari, alufa gbèro: nwọn si nràn Adonijah lọwọ.

1. A. Ọba 1