10. Igberaga Israeli si njẹri si i li oju rẹ̀; nwọn kò si yipadà si Oluwa Ọlọrun wọn, bẹ̃ni fun gbogbo eyi nwọn kò si wá a.
11. Efraimu pẹlu dabi òpe adàba ti kò li ọkàn; nwọn kọ si Egipti, nwọn lọ si Assiria.
12. Nigbati nwọn o lọ, emi o nà àwọn mi le wọn; emi o mu wọn wá ilẹ bi ẹiyẹ oju-ọrun; emi o nà wọn, bi ijọ-enia wọn ti gbọ́.
13. Egbe ni fun wọn! nitori nwọn ti sá kuro lọdọ mi: iparun ni fun wọn! nitori nwọn ti ṣẹ̀ si mi: bi o tilẹ ṣepe mo ti rà wọn padà, ṣugbọn nwọn ti ṣe eké si mi.
14. Nwọn kò si ti fi tọkàntọkàn ké pè mi, nigbati nwọn hu lori akete wọn: nwọn kó ara wọn jọ fun ọkà ati ọti-waini, nwọn si ṣọ̀tẹ si mi.
15. Bi mo ti dì, ti mo si fun apa wọn li okun, sibẹ̀ nwọn nrò ibi si mi.