Hos 6:4-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Efraimu, kili emi o ṣe si ọ? Juda, kili emi o ṣe si ọ? nitori ore nyin dàbi ikuku owurọ̀, ati bi ìri kùtukùtu ti o kọja lọ.

5. Nitorina ni mo ṣe fi ãké ké wọn lati ọwọ awọn woli; mo ti fi ọ̀rọ ẹnu mi pa wọn: ki idajọ rẹ le ri bi imọlẹ ti o jade lọ.

6. Nitori ãnu ni mo fẹ́, ki iṣe ẹbọ; ati ìmọ Ọlọrun jù ọrẹ-ẹbọ sisun lọ.

7. Ṣugbọn bi Adamu nwọn ti dá majẹmu kọja: nibẹ̀ ni nwọn ti ṣẹ̀tan si mi.

8. Gileadi ni ilu awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ, a si ti fi ẹ̀jẹ bà a jẹ.

9. Ati gẹgẹ bi ọwọ́ olè iti lùmọ dè enia, bẹ̃ni ẹgbẹ́ awọn alufa fohùnṣọ̀kan lati pania li ọ̀na: nitori nwọn dá ẹ̀ṣẹ nla.

10. Mo ti ri ohun buburu kan ni ile Israeli: agbère Efraimu wà nibẹ̀, Israeli ti bajẹ.

11. Iwọ Juda pẹlu, on ti gbe ikorè kalẹ fun ọ, nigbati mo ba yi igbekun awọn enia mi padà.

Hos 6