3. O di arakunrin rẹ̀ mu ni gigisẹ̀ ni inu, ati nipa ipá rẹ̀ o ni agbara pẹlu Ọlọrun.
4. Nitõtọ, o ni agbara lori angeli, o si bori: o sọkun, o si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ̀: o ri i ni Beteli, nibẹ̀ li o gbe ba wa sọ̀rọ;
5. Ani Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun; Oluwa ni iranti rẹ̀.
6. Nitorina, iwọ yipadà si Ọlọrun rẹ: pa ãnu ati idajọ mọ, ki o si ma duro de Ọlọrun rẹ nigbagbogbo.
7. Kenaani ni, iwọ̀n ẹtàn mbẹ li ọwọ́ rẹ̀: o fẹ lati ninilara.
8. Efraimu si wipe, Ṣugbọn emi di ọlọrọ̀, mo ti ri ini fun ara mi: ninu gbogbo lãlã mi nwọn kì yio ri aiṣedẽde kan ti iṣe ẹ̀ṣẹ lara mi.