Gẹn 49:8-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Judah, iwọ li ẹniti awọn arakunrin rẹ yio ma yìn; ọwọ́ rẹ yio wà li ọrùn awọn ọtá rẹ; awọn ọmọ baba rẹ yio foribalẹ niwaju rẹ.

9. Ọmọ kiniun ni Judah; ọmọ mi, ni ibi-ọdẹ ni iwọ ti goke: o bẹ̀rẹ, o ba bi kiniun, ati bi ogbó kiniun; tani yio lé e dide?

10. Ọpá-alade ki yio ti ọwọ́ Judah kuro, bẹ̃li olofin ki yio kuro lãrin ẹsẹ̀ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀.

11. Yio ma so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ ara àjara, ati ọmọ kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ mọ́ ara ãyo àjara; o ti fọ̀ ẹ̀wu rẹ̀ ninu ọtí-waini, ati aṣọ rẹ̀ ninu ẹ̀jẹ eso àjara:

12. Oju rẹ̀ yio pọ́n fun ọtí-waini, ehín rẹ̀ yio si funfun fun wàra.

13. Sebuloni ni yio ma gbé ebute okun: on ni yio si ma wà fun ebute ọkọ̀; ipinlẹ rẹ̀ yio si dé Sidoni.

14. Issakari ni kẹtẹkẹtẹ ti o lera, ti o dubulẹ lãrin awọn agbo-agutan.

15. O si ri pe isimi dara, ati ilẹ na pe o wuni; o si tẹ̀ ejiká rẹ̀ lati rẹrù, on si di ẹni nsìnrú.

16. Dani yio ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, bi ọkan ninu awọn ẹ̀ya Israeli.

17. Dani yio dabi ejò li ẹba ọ̀na, bi paramọlẹ li ọ̀na, ti ibù ẹṣin ṣán ni gigĩsẹ, tòbẹ̃ ti ẹniti o gùn u yio fi ṣubu sẹhin.

18. Emi ti duro dè ìgbala rẹ, OLUWA!

19. Gadi ọwọ́-ogun ni yio kọlù u: ṣugbọn on lé wọn.

20. Lati inu Aṣeri wá onjẹ rẹ̀ yio lọrá, on o si ma mú adidùn ọba wá.

21. Naftali li abo-agbọnrin ti o le sare: o funni li ọ̀rọ rere.

Gẹn 49