14. Issakari ni kẹtẹkẹtẹ ti o lera, ti o dubulẹ lãrin awọn agbo-agutan.
15. O si ri pe isimi dara, ati ilẹ na pe o wuni; o si tẹ̀ ejiká rẹ̀ lati rẹrù, on si di ẹni nsìnrú.
16. Dani yio ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, bi ọkan ninu awọn ẹ̀ya Israeli.
17. Dani yio dabi ejò li ẹba ọ̀na, bi paramọlẹ li ọ̀na, ti ibù ẹṣin ṣán ni gigĩsẹ, tòbẹ̃ ti ẹniti o gùn u yio fi ṣubu sẹhin.
18. Emi ti duro dè ìgbala rẹ, OLUWA!
19. Gadi ọwọ́-ogun ni yio kọlù u: ṣugbọn on lé wọn.
20. Lati inu Aṣeri wá onjẹ rẹ̀ yio lọrá, on o si ma mú adidùn ọba wá.
21. Naftali li abo-agbọnrin ti o le sare: o funni li ọ̀rọ rere.
22. Josefu li ẹka eleso pupọ̀, ẹka eleso pupọ̀ li ẹba kanga; ẹtun ẹniti o yọ si ori ogiri.
23. Awọn tafàtafa bà a ninu jẹ́ pọ̀ju, nwọn si tafà si i, nwọn si korira rẹ̀:
24. Ṣugbọn ọrun rẹ̀ joko li agbara, a si mú apa ọwọ́ rẹ̀ larale, lati ọwọ́ Alagbara Jakobu wá, (lati ibẹ̀ li oluṣọ-agutan, okuta Israeli,)
25. Ani lati ọwọ́ Ọlọrun baba rẹ wá, ẹniti yio ràn ọ lọwọ; ati lati ọwọ́ Olodumare wá, ẹniti yio fi ibukún lati oke ọrun busi i fun ọ, ibukún ọgbun ti o wà ni isalẹ, ibukún ọmú, ati ti inu.
26. Ibukún baba rẹ ti jù ibukún awọn baba nla mi lọ, titi dé opin oke aiyeraiye wọnni: nwọn o si ma gbé ori Josefu, ati li atari ẹniti a yàsọtọ lãrin awọn arakunrin rẹ̀.
27. Benjamini ni yio ma fàniya bi ikõkò: ni kutukutu ni yio ma jẹ ẹran-ọdẹ rẹ̀, ati li aṣalẹ ni yio ma pín ikogun rẹ̀.
28. Gbogbo wọnyi li awọn ẹ̀ya Israeli mejejila: eyi ni baba wọn si sọ fun wọn, o si sure fun wọn; olukuluku bi ibukún tirẹ̀, li o sure fun wọn.
29. O si kìlọ fun wọn, o si sọ fun wọn pe, A o kó mi jọ pọ̀ pẹlu awọn enia mi: ẹ sin mi pẹlu awọn baba mi ni ihò ti o mbẹ li oko Efroni ara Hitti.
30. Ninu ihò ti o mbẹ ninu oko Makpela ti mbẹ niwaju Mamre, ni ilẹ Kenaani, ti Abrahamu rà pẹlu oko lọwọ Efroni, ara Hitti fun ilẹ-isinku.