Gẹn 47:28-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Jakobu si wà li ọdún mẹtadilogun ni ilẹ Egipti; gbogbo ọjọ́ aiye Jakobu si jẹ́ ãdọjọ ọdún o di mẹta:

29. Akokò Israeli si sunmọ-etile ti yio kú: o si pè Josefu ọmọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bi emi ba ri ojurere li oju rẹ, jọ̃, fi ọwọ́ rẹ si abẹ itan mi, ki o si ṣe ãnu ati otitọ fun mi; emi bẹ̀ ọ, máṣe sin mi ni Egipti.

30. Ṣugbọn nigbati emi ba sùn pẹlu awọn baba mi, iwọ o gbe mi jade ni Egipti, ki o si sin mi ni iboji wọn. On si wipe, Emi o ṣe bi iwọ ti wi.

31. O si wipe, Bura fun mi. On si bura fun u. Israeli si tẹriba lori akete.

Gẹn 47