Gẹn 47:25-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Nwọn si wipe, Iwọ ti gbà ẹmi wa là: ki awa ki o ri ore-ọfẹ li oju oluwa mi, awa o si ma ṣe ẹrú Farao.

26. Josefu si ṣe e ni ilana ni ilẹ Egipti titi di oni-oloni pe, Farao ni yio ma ní idamarun; bikoṣe ilẹ awọn alufa nikan ni kò di ti Farao.

27. Israeli si joko ni ilẹ Egipti, ni ilẹ Goṣeni; nwọn si ní iní nibẹ̀, nwọn bísi i, nwọn si rẹ̀ gidigidi.

Gẹn 47