Gẹn 46:24-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Ati awọn ọmọ Naftali; Jahseeli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣillemu.

25. Wọnyi si li awọn ọmọ Bilha, ti Labani fi fun Rakeli ọmọbinrin rẹ̀, o si bí wọnyi fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ meje.

26. Gbogbo ọkàn ti o ba Jakobu wá si Egipti, ti o si ti inu Jakobu jade, li àika aya awọn ọmọ Jakobu, ọkàn na gbogbo jẹ́ mẹrindilãdọrin;

27. Ati awọn ọmọ Josefu ti a bí fun u ni Egipti jẹ́ ọkàn meji; gbogbo ọkàn ile Jakobu, ti o wá si ilẹ Egipti jẹ́ ãdọrin ọkàn.

28. O si rán Judah siwaju rẹ̀ si Josefu ki o kọju wọn si Goṣeni; nwọn si dé ilẹ Goṣeni.

Gẹn 46