18. Wọnyi li awọn ọmọ Silpa, ti Labani fi fun Lea ọmọbinrin rẹ̀, wọnyi li o si bí fun Jakobu, ọkàn mẹrindilogun.
19. Awọn ọmọ Rakeli aya Jakobu; Josefu ati Benjamini.
20. Manasse ati Efraimu li a si bí fun Josefu ni ilẹ Egipti, ti Asenati ọmọbinrin Potifera alufa Oni bí fun u.
21. Ati awọn ọmọ Benjamini; Bela, ati Bekeri, ati Aṣbeli, Gera, ati Naamani, Ehi, ati Roṣi, Muppimu, ati Huppimu, ati Ardi.
22. Wọnyi li awọn ọmọ Rakeli, ti a bí fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ mẹrinla.
23. Ati awọn ọmọ Dani; Huṣimu.
24. Ati awọn ọmọ Naftali; Jahseeli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣillemu.
25. Wọnyi si li awọn ọmọ Bilha, ti Labani fi fun Rakeli ọmọbinrin rẹ̀, o si bí wọnyi fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ meje.
26. Gbogbo ọkàn ti o ba Jakobu wá si Egipti, ti o si ti inu Jakobu jade, li àika aya awọn ọmọ Jakobu, ọkàn na gbogbo jẹ́ mẹrindilãdọrin;
27. Ati awọn ọmọ Josefu ti a bí fun u ni Egipti jẹ́ ọkàn meji; gbogbo ọkàn ile Jakobu, ti o wá si ilẹ Egipti jẹ́ ãdọrin ọkàn.
28. O si rán Judah siwaju rẹ̀ si Josefu ki o kọju wọn si Goṣeni; nwọn si dé ilẹ Goṣeni.
29. Josefu si dì kẹkẹ́ rẹ̀, o si lọ si Goṣeni lọ ipade Israeli baba rẹ̀, o si fi ara rẹ̀ hàn a; on si rọ̀ mọ́ ọ li ọrùn, o si sọkun si i li ọrùn pẹ titi.
30. Israeli si wi fun Josefu pe, Jẹ ki emi ki o kú wayi, bi mo ti ri oju rẹ yi, nitori ti iwọ wà lãye sibẹ̀.