16. Nigbati Josefu si ri Benjamini pẹlu wọn, o wi fun olori ile rẹ̀ pe, Mú awọn ọkunrin wọnyi rè ile, ki o si pa ẹran, ki o si pèse: nitori ti awọn ọkunrin wọnyi yio ba mi jẹun li ọjọkanri.
17. Ọkunrin na si ṣe bi Josefu ti wi; ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na lọ si ile Josefu.
18. Awọn ọkunrin na si mbẹ̀ru, nitori ti a mú wọn wá si ile Josefu; nwọn si wipe, Nitori owo ti a mú pada sinu àpo wa li akọ́wa li a ṣe mú wa wọle; ki o le fẹ wa lẹfẹ, ki o si le kọlù wa, ki o si le kó wa ṣe ẹrú ati awọn kẹtẹkẹtẹ wa.
19. Nwọn si sunmọ iriju ile Josefu, nwọn si bá a sọ̀rọ li ẹnu-ọ̀na ile na,
20. Nwọn si wipe, Alagba, nitõtọ li awa sọkalẹ wá ni iṣaju lati rà onjẹ:
21. O si ṣe, nigbati awa dé ile-èro, ti awa tú àpo wa, si kiyesi i, owo olukuluku wà li ẹnu àpo rẹ̀, owo wa ni pípe ṣánṣan: awa si tun mú u li ọwọ́ pada wá.
22. Owo miran li awa si mú li ọwọ́ wa sọkalẹ wá lati rà onjẹ: awa kò mọ̀ ẹniti o fi owo wa sinu àpo wa.
23. O si wi fun wọn pe, Alafia ni fun nyin, ẹ má bẹ̀ru: Ọlọrun nyin ati Ọlọrun baba nyin, li o fun nyin ni iṣura ninu àpo nyin: owo nyin dé ọwọ́ mi. O si mú Simeoni jade tọ̀ wọn wá.
24. Ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na wá si ile Josefu, o si fun wọn li omi, nwọn si wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn; o si fun awọn kẹtẹkẹtẹ wọn li ohun jijẹ.
25. Nwọn si ti mú ọrẹ na silẹ dè atibọ̀ Josefu lọsán: nitori ti nwọn gbọ́ pe nwọn o jẹun nibẹ̀.
26. Nigbati Josefu si wọlé, nwọn si mú ọrẹ ti o wà li ọwọ́ wọn fun u wá sinu ile, nwọn si tẹriba fun u ni ilẹ.