12. Ki ẹ si mú owo miran li ọwọ́ nyin; ati owo ti a mú pada wá li ẹnu àpo nyin, ẹ si tun mú u li ọwọ́ lọ; bọya o le ṣe èṣi:
13. Ẹ mú arakunrin nyin pẹlu, ẹ si dide, ẹ tun pada tọ̀ ọkunrin na lọ:
14. Ki Ọlọrun Olodumare ki o si fun nyin li ãnu niwaju ọkunrin na, ki o le rán arakunrin nyin ọhún wá, ati Benjamini. Bi a ba gbà mi li ọmọ, a gbà mi li ọmọ.
15. Awọn ọkunrin na si mú ọrẹ na, nwọn si mú iṣẹ́po owo meji li ọwọ́ wọn, ati Benjamini; nwọn si dide, nwọn si sọkalẹ lọ si Egipti, nwọn si duro niwaju Josefu.
16. Nigbati Josefu si ri Benjamini pẹlu wọn, o wi fun olori ile rẹ̀ pe, Mú awọn ọkunrin wọnyi rè ile, ki o si pa ẹran, ki o si pèse: nitori ti awọn ọkunrin wọnyi yio ba mi jẹun li ọjọkanri.
17. Ọkunrin na si ṣe bi Josefu ti wi; ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na lọ si ile Josefu.
18. Awọn ọkunrin na si mbẹ̀ru, nitori ti a mú wọn wá si ile Josefu; nwọn si wipe, Nitori owo ti a mú pada sinu àpo wa li akọ́wa li a ṣe mú wa wọle; ki o le fẹ wa lẹfẹ, ki o si le kọlù wa, ki o si le kó wa ṣe ẹrú ati awọn kẹtẹkẹtẹ wa.