Gẹn 41:5-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. O si sùn, o si lá alá lẹrinkeji: si kiyesi i, ṣiri ọkà meje yọ lara igi ọkà kan, ti o kún ti o si dara.

6. Si kiyesi i, ṣiri ọkà meje ti o fori, ti afẹfẹ íla-õrùn rẹ̀ dànu si rú jade lẹhin wọn.

7. Ṣiri meje ti o fori si mú ṣiri meje daradara ti o kún nì jẹ. Farao si jí, si kiyesi i, alá ni.

8. O si ṣe li owurọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò lelẹ; o si ranṣẹ o si pè gbogbo awọn amoye Egipti, ati gbogbo awọn ọ̀mọran ibẹ̀ wá: Farao si rọ́ alá rẹ̀ fun wọn: ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o le tumọ wọn fun Farao.

9. Nigbana li olori agbọti wi fun Farao pe, Emi ranti ẹ̀ṣẹ mi loni:

10. Farao binu si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si fi mi sinu túbu ni ile-túbu olori ẹṣọ́, emi ati olori alasè:

11. Awa si lá alá li oru kanna, emi ati on; awa lá alá olukuluku bi itumọ̀ alá tirẹ̀.

12. Ọdọmọkunrin kan ara Heberu, ọmọ-ọdọ olori ẹṣọ́, si wà nibẹ̀ pẹlu wa; awa si rọ́ wọn fun u, o si tumọ̀ alá wa fun wa, o tumọ̀ fun olukuluku gẹgẹ bi alá tirẹ̀.

13. O si ṣe bi o ti tumọ̀ fun wa, bẹ̃li o si ri; emi li o mú pada si ipò iṣẹ mi, on li o si sorọ̀.

14. Nigbana ni Farao ranṣẹ o si pè Josefu, nwọn si yara mú u jade kuro ninu ihò-túbu; o si fari rẹ̀, o si parọ̀ aṣọ rẹ̀, o si tọ̀ Farao wá.

15. Farao sí wi fun Josefu pe, Emi lá alá, kò si si ẹnikan ti o le tumọ̀ rẹ̀: emi si gburó rẹ pe, bi iwọ ba gbọ́ alá, iwọ le tumọ̀ rẹ̀.

16. Josefu si da Farao li ohùn pe, Ki iṣe emi: Ọlọrun ni yio fi idahùn alafia fun Farao.

17. Farao si wi fun Josefu pe, Li oju-alá mi, kiyesi i, emi duro lori bèbe odò.

18. Si kiyesi i, abo-malu meje ti o sanra, ti o si dara lati wò, jade lati inu odò na wa; nwọn si njẹ ni ẽsu-odò:

19. Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o joro, ti o burujù ni wiwò, ti o si rù, jade soke lẹhin wọn, nwọn buru tobẹ̃ ti emi kò ri irú wọn rí ni ilẹ Egipti.

20. Awọn abo-malu ti o rù, ti nwọn si buru ni wiwò, nwọn mú awọn abo-malu meje sisanra iṣaju wọnni jẹ:

21. Nigbati nwọn si jẹ wọn tán, a kò le mọ̀ pe, nwọn ti jẹ wọn: nwọn si buru ni wiwò sibẹ̀ gẹgẹ bi ìgba iṣaju. Bẹ̃ni mo jí.

22. Mo si ri li oju-alá mi, si kiyesi i, ṣiri ọkà meje jade lara igi ọkà kan, o kún o si dara:

23. Si kiyesi i, ṣiri ọkà meje rirẹ̀, ti o si fori, ati ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu, o rú jade lẹhin wọn:

Gẹn 41