Gẹn 41:30-50 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Lẹhin wọn ọdún meje ìyan si mbọ̀; gbogbo ọ̀pọ nì li a o si gbagbe ni ilẹ Egipti; ìyan na yio si run ilẹ;

31. A ki yio si mọ̀ ọ̀pọ na mọ́ ni ilẹ nitori ìyan na ti yio tẹle e, nitori yio mú gidigidi.

32. Nitorina li alá na ṣe dìlu ni meji fun Farao; nitoripe lati ọdọ Ọlọrun li a ti fi idi ọ̀ran na mulẹ, Ọlọrun yio si mú u ṣẹ kánkan.

33. Njẹ nisisiyi, ki Farao ki o wò amoye ati ọlọgbọ́n ọkunrin kan, ki o si fi i ṣe olori ilẹ Egipti.

34. Ki Farao ki o ṣe eyi, ki o si yàn awọn alabojuto si ilẹ yi, ki nwọn ki o si gbà idamarun ni ilẹ Egipti li ọdún meje ọ̀pọ nì.

35. Ki nwọn ki o si kó gbogbo onjẹ ọdún meje rere nì ti o dé, ki nwọn ki o si tò ọkà jọ si ọwọ́ Farao, ki nwọn ki o si pa onjẹ mọ́ ni ilu wọnni.

36. Onjẹ na ni yio si ṣe isigbẹ fun ilẹ dè ọdún meje ìyan na, ti mbọ̀wá si ilẹ Egipti; ki ilẹ ki o má ba run nitori ìyan na.

37. Ohun na si dara li oju Farao, ati li oju gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀.

38. Farao si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, A ha le ri ẹnikan bi irú eyi, ọkunrin ti Ẹmi Ọlọrun mbẹ ninu rẹ̀?

39. Farao si wi fun Josefu pe, Niwọnbi Ọlọrun ti fi gbogbo nkan yi hàn ọ, kò sí ẹniti o ṣe amoye ati ọlọgbọ́n bi iwọ:

40. Iwọ ni yio ṣe olori ile mi, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ li a o si ma ṣe akoso awọn enia mi: itẹ́ li emi o fi tobi jù ọ lọ:

41. Farao si wi fun Josefu pe, Wò o, emi fi ọ jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti.

42. Farao si bọ́ oruka ọwọ́ rẹ̀ kuro, o si fi bọ̀ Josefu li ọwọ́, o si wọ̀ ọ li aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si fi ẹ̀wọn wurà si i li ọrùn;

43. O si mu u gùn kẹkẹ́ keji ti o ní; nwọn si nké niwaju rẹ̀ pe, Kabiyesi: o si fi i jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti.

44. Farao si wi fun Josefu pe, Emi ni Farao, lẹhin rẹ ẹnikẹni kò gbọdọ gbé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ soke ni gbogbo ilẹ Egipti.

45. Farao si sọ orukọ Josefu ni Safnati-paanea; o si fi Asenati fun u li aya, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si jade lọ si ori ilẹ Egipti.

46. Josefu si jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nigbati o duro niwaju Farao ọba Egipti. Josefu si jade kuro niwaju Farao, o si là gbogbo ilẹ Egipti já.

47. Li ọdún meje ọ̀pọ nì, ilẹ si so eso ni ikunwọ-ikunwọ.

48. O si kó gbogbo onjẹ ọdún meje nì jọ, ti o wà ni ilẹ Egipti, o si fi onjẹ na ṣura ni ilu wọnni: onjẹ oko ilu ti o yi i ká, on li o kójọ sinu rẹ̀.

49. Josefu si kó ọkà jọ bi iyanrin okun lọ̀pọlọpọ; titi o fi dẹkun ati mã ṣirò; nitori ti kò ní iye.

50. A si bí ọmọkunrin meji fun Josefu, ki ọdún ìyan na ki o to dé, ti Asenati bí fun u, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni.

Gẹn 41