Gẹn 40:6-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Josefu si wọle tọ̀ wọn lọ li owurọ̀, o si wò wọn, si kiyesi i, nwọn fajuro.

7. O si bi awọn ijoye Farao ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ile túbu oluwa rẹ̀ pe, Ẽṣe ti oju nyin fi buru bẹ̃ loni?

8. Nwọn si wi fun u pe, Awa lá alá, kò si sí onitumọ̀ rẹ̀. Josefu si wi fun wọn pe, Ti Ọlọrun ki itumọ̀ iṣe ndan? emi bẹ̀ nyin, ẹ rọ́ wọn fun mi.

9. Olori agbọti si rọ́ alá tirẹ̀ fun Josefu, o si wi fun u pe, Li oju alá mi, kiyesi i, àjara kan wà niwaju mi,

10. Ati lara àjara na li ẹka mẹta wà; o si rudi, itana rẹ̀ si tú jade; ati ṣiri rẹ̀ si so eso-ájara ti o pọ́n.

11. Ago Farao si wà li ọwọ́ mi: emi si mú eso-àjara na, mo si fún wọn sinu ago Farao, mo si fi ago na lé Farao lọwọ.

12. Josefu si wi fun u pe, Itumọ̀ rẹ̀ li eyi: ẹka mẹta nì, ijọ́ mẹta ni:

13. Ni ijọ́ mẹta oni, ni Farao yio gbe ori rẹ soke yio si mú ọ pada si ipò rẹ: iwọ o si fi ago lé Farao li ọwọ́ gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju nigbati iwọ ti iṣe agbọti rẹ̀.

14. Ṣugbọn ki o ranti mi nigbati o ba dara fun ọ, ki o si fi iṣeun rẹ hàn fun mi, emi bẹ̀ ọ, ki o si da orukọ mi fun Farao, ki o si mú mi jade ninu ile yi.

15. Nitõtọ jíji li a jí mi tà lati ilẹ awọn Heberu wá: ati nihinyi pẹlu, emi kò ṣe nkan ti nwọn fi fi mi sinu ihò-túbu yi.

Gẹn 40