Gẹn 40:15-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Nitõtọ jíji li a jí mi tà lati ilẹ awọn Heberu wá: ati nihinyi pẹlu, emi kò ṣe nkan ti nwọn fi fi mi sinu ihò-túbu yi.

16. Nigbati olori alasè ri pe itumọ̀ alá na dara, o si wi fun Josefu pe, Emi wà li oju-alá mi pẹlu, si kiyesi i, emi rù agbọ̀n àkara funfun mẹta li ori mi:

17. Ati ninu agbọ̀n ti o wà loke li onirũru onjẹ sisè wà fun Farao; awọn ẹiyẹ si njẹ ẹ ninu agbọ̀n na ti o wà li ori mi.

18. Josefu si dahún o si wipe, itumọ̀ rẹ̀ li eyi: agbọ̀n mẹta nì, ijọ́ mẹta ni.

19. Ni ijọ́ mẹta oni ni Farao yio gbé ori rẹ kuro lara rẹ, yio si so ọ rọ̀ lori igi kan; awọn ẹiyẹ yio si ma jẹ ẹran ara rẹ kuro lara rẹ.

20. O si ṣe ni ijọ́ kẹta, ti iṣe ọjọ́ ibí Farao, ti o sè àse fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ gbogbo: o si gbé ori olori agbọti soke ati ti olori awọn alasè lãrin awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀.

21. O si tun mú olori agbọti pada si ipò rẹ̀; on si fi ago lé Farao li ọwọ́:

22. Ṣugbọn olori alasè li o sorọ̀: bi Josefu ti tumọ̀ alá na fun wọn.

23. Ṣugbọn olori agbọti kò ranti Josefu, o gbagbe rẹ̀.

Gẹn 40