16. Kaini si jade lọ kuro niwaju OLUWA, o si joko ni ilẹ Nodi, ni ìha ìla-õrùn Edeni.
17. Kaini si mọ̀ aya rẹ̀; o si loyun, o si bí Enoku: o si tẹ̀ ilu kan dó, o si sọ orukọ ilu na ni Enoku bi orukọ ọmọ rẹ̀ ọkunrin.
18. Fun Enoku li a bí Iradi: Iradi si bí Mehujaeli: Mehujaeli si bí Metuṣaeli: Metuṣaeli si bí Lameki.
19. Lameki si fẹ́ obinrin meji: orukọ ekini ni Ada, ati orukọ ekeji ni Silla.
20. Ada si bí Jabali: on ni baba irú awọn ti o ngbé agọ́, ti nwọn si li ẹran-ọ̀sin.
21. Orukọ arakunrin rẹ̀ ni Jubali: on ni baba irú gbogbo awọn ti nlò dùru ati fère.
22. Ati Silla on pẹlu bí Tubali-kaini, olukọni gbogbo ọlọnà idẹ, ati irin: arabinrin Tubali-kaini ni Naama.
23. Lameki si wi fun awọn aya rẹ̀ pe, Ada on Silla, ẹ gbọ́ ohùn mi; ẹnyin aya Lameki, ẹ fetisi ọ̀rọ mi: nitoriti mo pa ọkunrin kan si ẹ̀dun mi, ati ọdọmọkunrin kan si ipalara mi.
24. Bi a o gbẹsan Kaini lẹrinmeje, njẹ ti Lameki ni ìgba ãdọrin meje.
25. Adamu si tun mọ̀ aya rẹ̀, o si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti: o wipe, nitori Ọlọrun yàn irú-ọmọ miran fun mi ni ipò Abeli ti Kaini pa.