Gẹn 4:12-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nigbati iwọ ba ro ilẹ, lati isisiyi lọ, ki yio fi agbara rẹ̀ so eso fun ọ mọ; isansa ati alarinkiri ni iwọ o ma jẹ li aiye.

13. Kaini si wi fun OLUWA pe, ìya ẹ̀ṣẹ mi pọ̀ jù eyiti emi lè rù lọ.

14. Kiye si i, iwọ lé mi jade loni kuro lori ilẹ; emi o si di ẹniti o pamọ kuro loju rẹ; emi o si ma jẹ isansa ati alarinkiri li aiye; yio si ṣe ẹnikẹni ti o ba ri mi yio lù mi pa.

15. OLUWA si wi fun u pe, Nitorina ẹnikẹni ti o ba pa Kaini a o gbẹsan lara rẹ̀ lẹrinmeje. OLUWA si sàmi si Kaini lara, nitori ẹniti o ba ri i ki o má ba pa a.

16. Kaini si jade lọ kuro niwaju OLUWA, o si joko ni ilẹ Nodi, ni ìha ìla-õrùn Edeni.

17. Kaini si mọ̀ aya rẹ̀; o si loyun, o si bí Enoku: o si tẹ̀ ilu kan dó, o si sọ orukọ ilu na ni Enoku bi orukọ ọmọ rẹ̀ ọkunrin.

18. Fun Enoku li a bí Iradi: Iradi si bí Mehujaeli: Mehujaeli si bí Metuṣaeli: Metuṣaeli si bí Lameki.

19. Lameki si fẹ́ obinrin meji: orukọ ekini ni Ada, ati orukọ ekeji ni Silla.

20. Ada si bí Jabali: on ni baba irú awọn ti o ngbé agọ́, ti nwọn si li ẹran-ọ̀sin.

21. Orukọ arakunrin rẹ̀ ni Jubali: on ni baba irú gbogbo awọn ti nlò dùru ati fère.

22. Ati Silla on pẹlu bí Tubali-kaini, olukọni gbogbo ọlọnà idẹ, ati irin: arabinrin Tubali-kaini ni Naama.

Gẹn 4