Gẹn 39:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. A SI mú Josefu sọkalẹ wá si Egipti; Potifari, ijoye Farao kan, olori ẹṣọ́, ara Egipti, si rà a lọwọ awọn ara Iṣmaeli ti o mú u sọkalẹ wá sibẹ̀.

2. OLUWA si wà pẹlu Josefu, o si ṣe alasiki enia; o si wà ni ile oluwa rẹ̀ ara Egipti na.

3. Oluwa rẹ̀ si ri pe OLUWA pẹlu rẹ̀, ati pe, OLUWA mu ohun gbogbo ti o ṣe dara li ọwọ́ rẹ̀.

4. Josefu si ri ojurere li oju rẹ̀, on si nsìn i: o si fi i jẹ́ olori ile rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní on li o fi lé e lọwọ.

5. O si ṣe lati ìgba ti o ti fi Josefu jẹ́ olori ile rẹ̀, ati olori ohun gbogbo ti o ní, ni OLUWA busi ile ara Egipti na nitori Josefu: ibukún OLUWA si wà lara ohun gbogbo ti o ní ni ile ati li oko.

6. O si fi ohun gbogbo ti o ní si ọwọ́ Josefu; kò si mọ̀ ohun ti on ní bikoṣe onjẹ ti o njẹ. Josefu si ṣe ẹni daradara ati arẹwà enia.

7. O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni aya oluwa rẹ̀ gbé oju lé Josefu; o si wipe, Bá mi ṣe.

8. Ṣugbọn on kọ̀, o si wi fun aya oluwa rẹ̀ pe, kiyesi i, oluwa mi kò mọ̀ ohun ti o wà lọdọ mi ni ile, o si ti fi ohun gbogbo ti o ní lé mi lọwọ:

Gẹn 39