Gẹn 38:20-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Judah si rán ọmọ ewurẹ na lati ọwọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ara Adullamu na lọ, lati gbà ògo nì wá lọwọ obinrin na: ṣugbọn on kò ri i.

21. Nigbana li o bère lọwọ awọn ọkunrin ibẹ̀ na pe, Nibo ni panṣaga nì ngbé, ti o wà ni Enaimu li ẹba ọ̀na? Nwọn si wipe, Panṣaga kan kò sí nihin.

22. O si pada tọ̀ Judah lọ, o si wipe, Emi kò ri i; ati pẹlu awọn ọkunrin ara ibẹ̀ na wipe, Kò sí panṣaga kan nibẹ̀.

23. Judah si wipe, Jẹ ki o ma mú u fun ara rẹ̀, ki oju ki o má tì wa: kiyesi i, emi rán ọmọ ewurẹ yi, iwọ kò si ri i.

24. O si ṣe niwọ̀n oṣù mẹta lẹhin rẹ̀, ni a wi fun Judah pe, Tamari aya ọmọ rẹ ṣe àgbere; si kiyesi i pẹlu, o fi àgbere loyun. Judah si wipe, Mú u jade wá, ki a si dána sun u.

25. Nigbati a si mú u jade, o ranṣẹ si baba ọkọ rẹ̀ pe, ọkunrin ti o ní nkan wọnyi li emi yún fun: o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mọ̀ wọn, ti tani nkan wọnyi, èdidi, ati okùn, ati ọpá.

26. Judah si jẹwọ, o si wipe, O ṣe olododo jù mi lọ; nitori ti emi kò fi i fun Ṣela ọmọ mi. On kò si mọ̀ ọ mọ́ lai.

27. O si ṣe li akokò ti o nrọbí, si kiyesi i, ìbejì wà ni inu rẹ̀.

28. O si ṣe nigbati o nrọbí, ti ọkan yọ ọwọ́ jade: iyãgba si mú okùn ododó o so mọ́ ọ li ọwọ́, o wipe, Eyi li o kọ jade.

29. O si ṣe, bi o ti fà ọwọ́ rẹ̀ pada, si kiyesi i, aburo rẹ̀ jade: o si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yà? yiyà yi wà li ara rẹ, nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Peresi:

30. Nikẹhin li arakunrin rẹ̀ jade, ti o li okùn ododó li ọwọ́ rẹ̀: a si sọ orukọ rẹ̀ ni Sera.

Gẹn 38