Gẹn 36:10-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Esau; Elifasi, ọmọ Ada, aya Esau, Rueli, ọmọ Baṣemati, aya Esau.

11. Ati awọn ọmọ Elifasi ni Temani, Omari, Sefo, ati Gatamu, ati Kenasi.

12. Timna li o si ṣe àle Elifasi, ọmọ Esau; on si bí Amaleki fun Elifasi; wọnyi si li awọn ọmọ Ada, aya Esau.

13. Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli; Nahati, ati Sera, Ṣamma, ati Misa: awọn wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau.

14. Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, aya Esau: on si bí Jeuṣi fun Esau, ati Jaalamu, ati Kora.

15. Awọn wọnyi ni olori ninu awọn ọmọ Esau: awọn ọmọ Elifasi, akọ́bi Esau; Temani olori, Omari olori, Sefo olori, Kenasi olori,

Gẹn 36