2. O si tì awọn iranṣẹbinrin ati awọn ọmọ wọn ṣaju, ati Lea ati awọn ọmọ rẹ̀ tẹle wọn, ati Rakeli ati Josefu kẹhin.
3. On si kọja lọ siwaju wọn, o si wolẹ li ẹrinmeje titi o fi dé ọdọ arakunrin rẹ̀.
4. Esau si sure lati pade rẹ̀, o si gbá a mú, o si rọmọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu: nwọn si sọkun.
5. O si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri awọn obinrin ati awọn ọmọ; o si bi i pe, Tani wọnyi pẹlu rẹ? On si wipe, Awọn ọmọ ti Ọlọrun fi ore-ọfẹ fun iranṣẹ rẹ ni.