Gẹn 32:16-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. O si fi wọn lé ọwọ́ awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ni ọ̀wọ́ kọkan; o si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Ẹnyin ṣaju mi, ki ẹ si fi àlàfo si agbedemeji ọwọ́-ọwọ.

17. O si fi aṣẹ fun eyiti o tète ṣaju wipe, Nigbati Esau, arakunrin mi, ba pade rẹ, ti o si bi ọ wipe, Ti tani iwọ? nibo ni iwọ si nrè? ati ti tani wọnyi niwaju rẹ?

18. Nigbana ni ki iwọ ki o wipe, Ti Jakobu iranṣẹ rẹ ni; ọrẹ ti o rán si Esau oluwa mi ni: si kiyesi i, on tikalarẹ̀ si mbẹ lẹhin wa.

19. Bẹ̃li o si fi aṣẹ fun ekeji, ati fun ẹkẹta, ati fun gbogbo awọn ti o tẹle ọwọ́ wọnni wipe, Bayibayi ni ki ẹnyin ki o wi fun Esau nigbati ẹnyin ba ri i.

20. Ki ẹnyin ki o wi pẹlu pe, Kiyesi i, Jakobu iranṣẹ rẹ mbọ̀ lẹhin wa. Nitori ti o wipe, Emi o fi ọrẹ ti o ṣaju mi tù u loju, lẹhin eyini emi o ri oju rẹ̀, bọya yio tẹwọgbà mi.

21. Bẹ̃li ọrẹ na si kọja lọ niwaju rẹ̀: on tikalarẹ̀ si sùn li oru na ninu awọn ẹgbẹ.

22. O si dide li oru na, o si mú awọn aya rẹ̀ mejeji, ati awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ mejeji, ati awọn ọmọ rẹ̀ mọkọkanla, o si kọja iwọdò Jabboku.

23. O si mú wọn, o si rán wọn si oke odò na, o si rán ohun ti o ní kọja si oke odò.

24. O si kù Jakobu nikan; ọkunrin kan si mbá a jijakadi titi o fi di afẹmọ́jumọ.

25. Nigbati o si ri pe on kò le dá a, o fọwọkàn a ni ihò egungun itan rẹ̀; ihò egungun itan Jakobu si yẹ̀ li orike, bi o ti mbá a jijakadi.

26. O si wipe, Jẹ ki emi ki o lọ nitori ti ojúmọ mọ́ tán. On si wipe, Emi ki yio jẹ ki iwọ ki o lọ, bikoṣepe iwọ ba sure fun mi.

27. O si bi i pe, Orukọ rẹ? On si dahùn pe, Jakobu.

28. O si wipe, A ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli: nitoripe, iwọ ti ba Ọlọrun ati enia jà, iwọ si bori.

29. Jakobu si bi i o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, sọ orukọ rẹ fun mi. On si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi mbère orukọ mi? o si sure fun u nibẹ̀.

Gẹn 32