26. Labani si wi fun Jakobu pe, Kini iwọ ṣe nì, ti iwọ tàn mi jẹ ti iwọ si kó awọn ọmọbinrin mi lọ bi ìgbẹsin ti a fi idà mú?
27. Ẽṣe ti iwọ fi salọ li aṣíri, ti iwọ si tàn mi jẹ; ti iwọ kò si wi fun mi ki emi ki o le fi ayọ̀ ati orin, ati ìlu, ati dùru, sìn ọ;
28. Ti iwọ kò si jẹ ki emi fi ẹnu kò awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin mi li ẹnu? iwọ ṣiwere li eyiti iwọ ṣe yi.
29. O wà ni ipa mi lati ṣe nyin ni ibi: ṣugbọn Ọlọrun baba nyin ti sọ fun mi li oru aná pe, Kiyesi ara rẹ ki iwọ ki o máṣe bá Jakobu sọ rere tabi buburu.
30. Ati nisisiyi, iwọ kò le ṣe ailọ, nitori ti ọkàn rẹ fà gidigidi si ile baba rẹ, ṣugbọn ẽhaṣe ti iwọ fi jí awọn oriṣa mi lọ?
31. Jakobu si dahùn o si wi fun Labani pe, Nitori ti mo bẹ̀ru ni: nitori ti mo wipe, iwọ le fi agbara gbà awọn ọmọbinrin rẹ lọwọ mi.
32. Lọwọ ẹnikẹni ti iwọ ba ri awọn oriṣa rẹ ki o máṣe wà lãye: li oju awọn arakunrin wa wọnyi, wá ohun ti iṣe tirẹ lọdọ mi, ki o si mú u si ọdọ rẹ. Jakobu kò sa mọ̀ pe Rakeli ti jí wọn.
33. Labani si wọ̀ inu agọ́ Jakobu lọ, ati inu agọ́ Lea, ati inu agọ́ awọn iranṣẹbinrin mejeji; ṣugbọn kò ri wọn. Nigbana li o jade kuro ninu agọ́ Lea, o si wọ̀ inu agọ́ Rakeli lọ.
34. Rakeli si gbé awọn ere na, o si fi wọn sinu gãri ibakasiẹ, o si joko le wọn. Labani si wá gbogbo agọ́ ṣugbọn kò ri wọn.