11. Angeli Ọlọrun si sọ fun mi li oju-alá pe, Jakobu: emi si wipe, Emi niyi.
12. O si wipe, Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò, gbogbo awọn obukọ ti ngùn awọn ẹran li o ṣe tototó, abilà, ati alamì: nitori ti emi ti ri ohun gbogbo ti Labani nṣe si ọ.
13. Emi li Ọlọrun Beteli, nibiti iwọ gbé ta oróro si ọwọ̀n, nibiti iwọ gbè jẹ́ ẹjẹ́ fun mi: dide nisisiyi, jade kuro ni ilẹ yi, ki o si pada lọ si ilẹ ti a bi ọ.
14. Rakeli ati Lea si dahùn nwọn si wi fun u pe, Ipín, tabi ogún kan ha tun kù fun wa mọ́ ni ile baba wa?
15. Alejò ki on nkà wa si? nitori ti o ti tà wa; o si ti mù owo wa jẹ gúdu-gudu.
16. Nitori ọrọ̀ gbogbo ti Ọlọrun ti gbà lọwọ baba wa, eyinì ni ti wa, ati ti awọn ọmọ wa: njẹ nisisiyi ohunkohun ti Ọlọrun ba sọ fun ọ, on ni ki o ṣe.
17. Nigbana ni Jakobu dide, o si gbé awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn aya rẹ̀ gùn ibakasiẹ.
18. O si kó gbogbo ẹran rẹ̀ lọ, ati gbogbo ẹrù ti o ní, ẹran ti o ní fun ara rẹ̀, ti o ní ni Padan-aramu, lati ma tọ̀ Isaaki baba rẹ̀ lọ ni ilẹ Kenaani.
19. Labani si lọ irẹrun agutan rẹ̀: Rakeli si ti jí awọn ere baba rẹ̀ lọ.
20. Jakobu si tàn Labani ara Siria jẹ, niti pe kò wi fun u ti o fi salọ.
21. Bẹ̃li o kó ohun gbogbo ti o ní salọ: o si dide, o si kọja odò, o si kọju rẹ̀ si oke Gileadi.
22. A si wi fun Labani ni ijọ́ kẹta pe, Jakobu salọ.
23. O si mú awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu rẹ̀, o si lepa rẹ̀ ni ìrin ijọ́ meje: o si bá a li oke Gileadi.
24. Ọlọrun si tọ̀ Labani, ara Siria wá li oru li oju-alá, o si wi fun u pe, Kiyesi ara rẹ, ki iwọ ki o máṣe bá Jakobu sọ rere tabi buburu.
25. Nigbana ni Labani bá Jakobu. Jakobu ti pa agọ́ rẹ̀ li oke na: ati Labani pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ dó li oke Gileadi.