7. Bilha, iranṣẹbinrin Rakeli, si tun yún, o si bi ọmọkunrin keji fun Jakobu.
8. Rakeli si wipe, Ijakadi nla ni mo fi bá arabinrin mi ja, emi si dá a: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Naftali.
9. Nigbati Lea ri pe on dẹkun ọmọ bíbi, o si mú Silpa, iranṣẹbinrin rẹ̀, o si fi i fun Jakobu li aya.
10. Silpa, iranṣẹbinrin Lea, si bí ọmọkunrin kan fun Jakobu.
11. Lea si wipe, Ire de: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gadi.
12. Silpa iranṣẹbinrin Lea si bí ọmọkunrin keji fun Jakobu.
13. Lea si wipe, Alabukún fun li emi, nitori ti awọn ọmọbinrin yio ma pè mi li alabukún fun: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Aṣeri.