Gẹn 30:2-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Jakobu si binu si Rakeli: o si wipe, Emi ha wà ni ipò Ọlọrun, ẹniti o dù ọ li ọmọ bíbi?

3. On si wipe, Wò Bilha iranṣẹbinrin mi, wọle tọ̀ ọ; on ni yio si bí lori ẽkun mi, ki a le gbé mi ró pẹlu nipasẹ rẹ̀.

4. O si fi Bilha, iranṣẹbinrin rẹ̀, fun u li aya: Jakobu si wọle tọ̀ ọ.

5. Bilha si yún, o si bí ọmọkunrin kan fun Jakobu.

6. Rakeli si wipe, Ọlọrun ti ṣe idajọ mi, o si ti gbọ́ ohùn mi, o si fi ọmọkunrin kan fun mi pẹlu: nitorina li o ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Dani.

7. Bilha, iranṣẹbinrin Rakeli, si tun yún, o si bi ọmọkunrin keji fun Jakobu.

8. Rakeli si wipe, Ijakadi nla ni mo fi bá arabinrin mi ja, emi si dá a: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Naftali.

9. Nigbati Lea ri pe on dẹkun ọmọ bíbi, o si mú Silpa, iranṣẹbinrin rẹ̀, o si fi i fun Jakobu li aya.

10. Silpa, iranṣẹbinrin Lea, si bí ọmọkunrin kan fun Jakobu.

11. Lea si wipe, Ire de: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gadi.

Gẹn 30