Gẹn 30:11-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Lea si wipe, Ire de: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gadi.

12. Silpa iranṣẹbinrin Lea si bí ọmọkunrin keji fun Jakobu.

13. Lea si wipe, Alabukún fun li emi, nitori ti awọn ọmọbinrin yio ma pè mi li alabukún fun: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Aṣeri.

14. Li akokò ìgba ikore alikama, Reubeni si lọ, o si ri eso mandraki ni igbẹ́, o si mú wọn fun Lea iya rẹ̀ wá ile. Nigbana ni Rakeli wi fun Lea pe, Emi bẹ̀ ọ, bùn mi ninu mandraki ọmọ rẹ.

15. O si wi fun u pe, Iṣe nkan kekere ti iwọ gbà ọkọ lọwọ mi? iwọ si nfẹ́ gbà mandraki ọmọ mi pẹlu? Rakeli si wipe, Nitori na ni yio ṣe sùn tì ọ li alẹ yi nitori mandraki ọmọ rẹ.

16. Jakobu si ti inu oko dé li aṣalẹ, Lea si jade lọ ipade rẹ̀, o si wipe, Iwọ kò le ṣe aima wọle tọ̀ mi wá, nitori ti emi ti fi mandraki ọmọ mi bẹ̀ ọ li ọ̀wẹ. On si sùn tì i li oru na.

17. Ọlọrun si gbọ́ ti Lea, o si yún, o si bí ọmọkunrin karun fun Jakobu.

18. Lea si wipe, Ọlọrun san ọ̀ya mi fun mi, nitori ti mo fi iranṣẹbinrin mi fun ọkọ mi; o si pè orukọ rẹ̀ ni Issakari.

19. Lea si tun yún, o si bí ọmọkunrin kẹfa fun Jakobu.

20. Lea si wipe, Ọlọrun ti fun mi li ẹ̀bun rere; nigbayi li ọkọ mi yio tó ma bá mi gbé, nitori ti mo bí ọmọkunrin mẹfa fun u: o si pè orukọ rẹ̀ ni Sebuluni.

21. Nikẹhin rẹ̀ li o si bí ọmọbinrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Dina.

22. Ọlọrun si ranti Rakeli, Ọlọrun si gbọ́ tirẹ̀, o si ṣí i ni inu.

23. O si yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Ọlọrun mú ẹ̀gan mi kuro:

24. O si pè orukọ rẹ̀ ni Josefu; o si wipe, Ki OLUWA ki o fi ọmọkunrin kan kún u fun mi pẹlu.

Gẹn 30