Jakobu si ti inu oko dé li aṣalẹ, Lea si jade lọ ipade rẹ̀, o si wipe, Iwọ kò le ṣe aima wọle tọ̀ mi wá, nitori ti emi ti fi mandraki ọmọ mi bẹ̀ ọ li ọ̀wẹ. On si sùn tì i li oru na.