9. Lọ nisisiyi sinu agbo-ẹran, ki o si mu ọmọ ewurẹ meji daradara fun mi lati ibẹ̀ wá: emi o si sè wọn li ẹran adidùn fun baba rẹ, bi irú eyiti o fẹ́:
10. Iwọ o si gbé e tọ̀ baba rẹ lọ, ki o le jẹ, ki o le súre fun ọ, ki on to kú.
11. Jakobu si wi fun Rebeka iya rẹ̀ pe, Kiyesi i, enia onirun ni Esau arakunrin mi, alara ọbọrọ́ si li emi:
12. Bọya baba mi yio fọwọbà mi, emi o si dabi ẹlẹ̀tan fun u; emi o si mu egún wá si ori mi ki yio ṣe ibukún.
13. Iya rẹ̀ si wi fun u pe, lori mi ni ki egún rẹ wà, ọmọ mi: sá gbọ́ ohùn mi, ki o si lọ mu wọn fun mi wá.
14. O si lọ, o mu wọn, o si fà wọn tọ̀ iya rẹ̀ wá: iya rẹ̀ si sè ẹran adidùn; bi irú eyiti baba rẹ̀ fẹ́.
15. Rebeka si mu ãyo aṣọ Esau, ọmọ rẹ̀ ẹgbọ́n, ti o wà lọdọ rẹ̀ ni ile, o si fi wọn wọ̀ Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo:
16. O si fi awọ awọn ọmọ ewurẹ wọnni bò o li ọwọ́, ati si ọbọrọ́ ọrùn rẹ̀:
17. O si fi ẹran adidùn na, ati àkara ti o ti pèse, le Jakobu, ọmọ rẹ̀, lọwọ.
18. O si tọ̀ baba rẹ̀ wá, o wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi; iwọ tani nì ọmọ mi?
19. Jakobu si wi fun baba rẹ̀ pe, Emi Esau akọ́bi rẹ ni; emi ti ṣe gẹgẹ bi o ti sọ fun mi, dide joko, emi bẹ̀ ọ, ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ mi, ki ọkàn rẹ le súre fun mi.