Esau si korira Jakobu nitori ire ti baba rẹ̀ su fun u: Esau si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọjọ́ ọ̀fọ baba mi sunmọ-etile; nigbana li emi o pa Jakobu, arakunrin mi.