1. O si ṣe, ti Isaaki gbó, ti oju rẹ̀ si nṣe bàibai, tobẹ̃ ti kò le riran, o pè Esau, ọmọ rẹ̀ akọ́bi, o si wi fun u pe, Ọmọ mi: on si dá a li ohùn pe, Emi niyi.
2. O si wipe, Wò o na, emi di arugbo, emi kò si mọ̀ ọjọ́ ikú mi;
3. Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ohun ọdẹ rẹ, apó rẹ, ati ọrun rẹ, ki o si jade lọ si igbẹ́ ki o si pa ẹran-igbẹ́ fun mi wá: