27. Isaaki si bi wọn pe, Nitori kili ẹnyin ṣe tọ̀ mi wá, ẹnyin sa korira mi, ẹnyin si ti lé mi kuro lọdọ nyin?
28. Nwọn si wipe, Awa ri i nitõtọ pe, OLUWA wà pẹlu rẹ: awa si wipe, Njẹ nisisiyi jẹ ki ibura ki o wà lãrin wa, ani lãrin tawa tirẹ, ki awa ki o si ba iwọ dá majẹmu;
29. Pe iwọ ki yio ṣe wa ni ibi, bi awa kò si ti fọwọkàn ọ, ati bi awa kò si ti ṣe ọ ni nkan bikoṣe rere, ti awa si rán ọ jade li alafia: nisisiyi ẹni-ibukún OLUWA ni iwọ.
30. O si sè àse fun wọn, nwọn si jẹ, nwọn si mu.
31. Nwọn si dide ni kutukutu owurọ̀, nwọn si bura fun ara wọn: Isaaki si rán wọn pada lọ, nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀ li alafia.
32. O si ṣe li ọjọ́ kanna li awọn ọmọ-ọdọ Isaaki wá, nwọn si rò fun u niti kanga ti nwọn wà, nwọn si wi fun u pe, Awa kàn omi.