11. Abimeleki si kìlọ fun gbogbo awọn enia rẹ̀ wipe, Ẹnikẹni ti o ba tọ́ ọkunrin yi tabi aya rẹ̀, kikú ni yio kú.
12. Nigbana ni Isaaki funrugbìn ni ilẹ na, o si ri ọrọrún mu li ọdún na; OLUWA si busi i fun u:
13. Ọkunrin na si di pupọ̀, o si nlọ si iwaju, o si npọ̀ si i titi o fi di enia nla gidigidi.
14. Nitori ti o ni agbo-agutan, ati ini agbo-ẹran nla ati ọ̀pọlọpọ ọmọ-ọdọ: awọn ara Filistia si ṣe ilara rẹ̀.