Gẹn 26:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ÌYAN kan si mu ni ilẹ na, lẹhin ìyan ti o tetekọ mu li ọjọ́ Abrahamu. Isaaki si tọ̀ Abimeleki, ọba awọn ara Filistia lọ, si Gerari.

2. OLUWA si farahàn a, o si wipe, Máṣe sọkalẹ lọ si Egipti; joko ni ilẹ ti emi o wi fun ọ.

3. Mã ṣe atipo ni ilẹ yi, emi o si pẹlu rẹ, emi o si bukún u fun ọ; nitori iwọ ati irú-ọmọ rẹ, li emi o fi gbogbo ilẹ wọnyi fun, emi o si mu ara ti mo bú fun Abrahamu, baba rẹ, ṣẹ.

4. Emi o si mu irú-ọmọ rẹ bisi i bi irawọ oju-ọrun, emi o si fi gbogbo ilẹ wọnyi fun irú-ọmọ rẹ; ati nipasẹ irú-ọmọ rẹ li a o bukún gbogbo orilẹ-ède aiye;

5. Nitoriti Abrahamu gbà ohùn mi gbọ́, o si pa ìlọ mi, aṣẹ mi, ìlana mi, ati ofin mi mọ́.

6. Isaaki si joko ni Gerari.

7. Awọn ọkunrin ibẹ̀ na bi i lẽre niti aya rẹ̀: o si wipe, Arabinrin mi ni: nitoriti o bẹ̀ru ati wipe, Aya mi ni; o ni, ki awọn ọkunrin ibẹ̀ na ki o má ba pa mi nitori Rebeka; nitoriti on li ẹwà lati wò.

8. O si ṣe nigbati o joko nibẹ̀ pẹ titi, ni Abimeleki, ọba awọn ara Filistia, wò ode li ojuferese, o si ri, si kiyesi i, Isaaki mba Rebeka aya rẹ̀ wẹ́.

Gẹn 26