27. O si wipe, Olubukún li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, ti kò jẹ ki ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ ki o yẹ̀ kuro lọdọ, oluwa mi, niti emi, OLUWA fi ẹsẹ̀ mi le ọ̀na ile awọn arakunrin baba mi.
28. Omidan na si sure, o si rò nkan wọnyi fun awọn ara ile iya rẹ̀.
29. Rebeka si li arakunrin kan, orukọ rẹ̀ si ni Labani: Labani si sure jade tọ̀ ọkunrin na lọ si ibi kanga.
30. O si ṣe, bi o ti ri oruka, ati jufù li ọwọ́ arabinrin rẹ̀, ti o si gbọ́ ọ̀rọ Rebeka arabinrin rẹ̀ pe, Bayi li ọkunrin na ba mi sọ; bẹ̃li o si tọ̀ ọkunrin na wá; si kiyesi i, o duro tì awọn ibakasiẹ rẹ̀ leti kanga na.
31. O si wipe, Wọle, iwọ ẹni-ibukún OLUWA; ẽṣe ti iwọ fi duro lode? mo sá ti pèse àye silẹ ati àye fun awọn ibakasiẹ.
32. Ọkunrin na si wọle na wá; o si tú awọn ibakasiẹ, o si fun awọn ibakasiẹ, ni koriko ati sakasáka, ati omi fun u lati wẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, ati ẹsẹ̀ awọn ọkunrin ti o pẹlu rẹ̀.
33. A si gbé onjẹ kalẹ fun u lati jẹ: ṣugbọn on si wipe, Emi ki yio jẹun titi emi o fi jiṣẹ mi tán. On si wipe, Ma wi.
34. O si wipe, Ọmọ-ọdọ Abrahamu li emi iṣe.
35. OLUWA si ti bukún fun oluwa mi gidigidi; o si di pupọ̀: o si fun u li agutan, ati mãlu, ati fadaka, ati wurà, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, ati ibakasiẹ, ati kẹtẹkẹtẹ.
36. Sara, aya oluwa mi, si bí ọmọ kan fun oluwa mi nigbati on (Sara) gbó tán: on li o si fi ohun gbogbo ti o ni fun.
37. Oluwa mi si mu mi bura, wipe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ obinrin fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani ni ilẹ ẹniti emi ngbé:
38. Bikoṣe ki iwọ ki o lọ si ile baba mi, ati si ọdọ awọn ibatan mi, ki o si fẹ́ aya fun ọmọ mi.
39. Emi si wi fun oluwa mi pe, Bọya obinrin na ki yio tẹle mi.